s-1
| Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. |
s-2
| Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi gbogbo. |
s-3
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. |
s-4
| Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. |
s-5
| Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. |
s-6
| Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfurufú kí ó wà ní àárin àwọn omi láti pààlà sí àárin àwọn omi.” |
s-7
| Ọlọ́run sì dá òfurufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfurufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-8
| Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. |
s-9
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-10
| Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “Ilẹ̀” àti àpapọ̀ omi ní “Òkun:” Ọlórun sì rí i wí pé ó dára. |
s-11
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko tí yóò máa mú èṣo wá àti igi tí yóò máa so èṣo ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-12
| Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èṣo ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èṣo, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. |
s-13
| Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta. |
s-14
| Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, |
s-15
| Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-16
| Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá-ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. |
s-17
| Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, |
s-18
| láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárin ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-19
| Àsálẹ́ àti òwúrọ jẹ́ ọjọ́ kẹrin. |
s-20
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfurufú.” |
s-21
| Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá-ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-22
| Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” |
s-23
| Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kárùn-ún. |
s-24
| Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-25
| Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-26
| Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ohun ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” |
s-27
| “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, Òun náà ni olè àti ọlọ́sà. |
s-28
| Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. |
s-29
| Òun ni osọ́nà yóò ṣí ìlẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ , ó sì se amọ̀nà wọn jáde. |
s-30
| Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò ṣíwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. |
s-31
| Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” |
s-32
| Òwe yìí ni Jésù pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí jẹ́ tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn. |
s-33
| Nítorí náà Jésù tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. |
s-34
| Olè àti ọlọ́sà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ ti wọn. |
s-35
| Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, Òun ni a ó gbà là, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. |
s-36
| Olè kìí wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀. |
s-37
| “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. |
s-38
| Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kìí ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kìí ṣe tirẹ̀, ó rí ìkokò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. |
s-39
| Òun sá lọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. |
s-40
| Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kìí ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn ó sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùsọ́-àgùntàn kan. |
s-41
| Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. |
s-42
| Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” |
s-43
| Nítorí náà ìyapa tún wà láàrin àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. |
s-44
| Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?” |
s-45
| Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mi èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?” |
s-46
| Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni. |
s-47
| Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì, |
s-48
| Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.” |
s-49
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. |
s-50
| Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. |
s-51
| Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. |
s-52
| Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.” |
s-53
| Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú. |
s-54
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?” |
s-55
| Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.” |
s-56
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “A kò ha ti kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? |
s-57
| Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. |
s-58
| Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” |
s-59
| Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn. |
s-60
| Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” |
s-61
| Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́ . |
s-62
| Ara ọkùnrin kan sì ṣe aláìdá, Lásárù, ará Bẹ́tẹ́nì, tí í ṣe ìlú Màríà àti Mátà arábìnrin rẹ̀. |
s-63
| (Màríà náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lásárù í ṣe, ara ẹni tí kò dá.) |
s-64
| Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ ránsẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.” |
s-65
| Nígbà tí Jésù sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kìí ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” |
s-66
| Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.” |
s-67
| Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lásárù ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.” |
s-68
| Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá se pé ó sùn, yóò sàn.” |
s-69
| Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn. |
s-70
| Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú, |
s-71
| Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. |
s-72
| “Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.” |
s-73
| Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná, |
s-74
| Ǹjẹ́ Bétanì súnmọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún: |
s-75
| Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Mátà àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. |
s-76
| Nítorí náà, nígbà tí Mátà gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé. |
s-77
| Nígbà náà, ni Mátà wí fún Jésù pé, “Olúwa, ì bá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. |
s-78
| Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.” |
s-79
| Mátà wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.” |
s-80
| Jésù wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: |
s-81
| Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?” |
s-82
| Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.” |
s-83
| Nígbà tí ó sì ti wí èyí tán, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” |
s-84
| Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. |
s-85
| Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Mátà ti pàdé rẹ̀. |
s-86
| Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀. |
s-87
| Nígbà tí Màríà sì dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbáṣe pé ìwọ ti wà níhín-ín, arákùnrin mi kì bá kú.” |
s-88
| Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.” |
s-89
| Jésù sọkún. |
s-90
| Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” |
s-91
| Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣeé kí ọkùnrin yìí má kú bí?” |
s-92
| Nígbà náà ni Jésù tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. |
s-93
| Jésù wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Màtá, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ijọ́ kẹrin tí ó tí kú.” |
s-94
| Jésù wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ ó rí ògo Ọlọ́run?” |
s-95
| Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. |
s-96
| Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.” |
s-97
| Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lásárù, jáde wá.” |
s-98
| Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó má a lọ!” |
s-99
| Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe, ṣe gbà á gbọ́. |
s-100
| Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe. |