s-1
| Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. |
s-2
| Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi gbogbo. |
s-3
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. |
s-4
| Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. |
s-5
| Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. |
s-6
| Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfurufú kí ó wà ní àárin àwọn omi láti pààlà sí àárin àwọn omi.” |
s-7
| Ọlọ́run sì dá òfurufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfurufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-8
| Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. |
s-9
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-10
| Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “Ilẹ̀” àti àpapọ̀ omi ní “Òkun:” Ọlórun sì rí i wí pé ó dára. |
s-11
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko tí yóò máa mú èṣo wá àti igi tí yóò máa so èṣo ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-12
| Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èṣo ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èṣo, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. |
s-13
| Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta. |
s-14
| Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, |
s-15
| Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-16
| Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá-ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. |
s-17
| Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, |
s-18
| láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárin ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-19
| Àsálẹ́ àti òwúrọ jẹ́ ọjọ́ kẹrin. |
s-20
| Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfurufú.” |
s-21
| Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá-ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-22
| Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” |
s-23
| Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kárùn-ún. |
s-24
| Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. |
s-25
| Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. |
s-26
| Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ohun ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” |