s-1
| “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, Òun náà ni olè àti ọlọ́sà. |
s-2
| Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. |
s-3
| Òun ni osọ́nà yóò ṣí ìlẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ , ó sì se amọ̀nà wọn jáde. |
s-4
| Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò ṣíwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. |
s-5
| Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” |
s-6
| Òwe yìí ni Jésù pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí jẹ́ tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn. |
s-7
| Nítorí náà Jésù tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. |
s-8
| Olè àti ọlọ́sà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ ti wọn. |
s-9
| Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, Òun ni a ó gbà là, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. |
s-10
| Olè kìí wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀. |
s-11
| “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. |
s-12
| Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kìí ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kìí ṣe tirẹ̀, ó rí ìkokò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. |
s-13
| Òun sá lọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. |
s-14
| Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kìí ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn ó sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùsọ́-àgùntàn kan. |
s-15
| Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. |
s-16
| Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.” |
s-17
| Nítorí náà ìyapa tún wà láàrin àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. |
s-18
| Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?” |
s-19
| Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mi èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?” |
s-20
| Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni. |
s-21
| Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì, |
s-22
| Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.” |
s-23
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. |
s-24
| Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. |
s-25
| Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. |
s-26
| Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.” |
s-27
| Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú. |
s-28
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?” |
s-29
| Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.” |
s-30
| Jésù dá wọn lóhùn pé, “A kò ha ti kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? |
s-31
| Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. |
s-32
| Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” |
s-33
| Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn. |
s-34
| Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” |
s-35
| Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́ . |