Sentence view

Universal Dependencies - Yoruba - YTB

LanguageYoruba
ProjectYTB
Corpus Parttest

Text: -


[1] tree
Wọn lọ si apákejì adágún ẹba ilẹ̀ àwọn ará Gádárà.
s-1
MARK_5.1
Wọn lọ si apákejì adágún ní ẹba ilẹ̀ àwọn ará Gádárà.
And they came over unto the other side of the sea, into the country of the Gadarenes.
[2] tree
Jésù ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan ó ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì pàdé rẹ̀.
s-2
MARK_5.2
Bí Jésù sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀.
And when he was come out of the ship, immediately there met him out of the tombs a man with an unclean spirit,
[3] tree
Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, ẹni ó é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n le é.
s-3
MARK_5.3
Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é.
Who had his dwelling among the tombs; and no man could bind him, no, not with chains:
[4] tree
Nítorí nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, ó ń a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. ẹnìkan ó agbára láti káwọ́ rẹ̀.
s-4
MARK_5.4
Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀.
Because that he had been often bound with fetters and chains, and the chains had been plucked asunder by him, and the fetters broken in pieces: neither could any man tame him.
[5] tree
Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara ó ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
s-5
MARK_5.5
Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
And always, night and day, he was in the mountains, and in the tombs, crying, and cutting himself with stones.
[6] tree
Nígbà ó Jésù látòkèrè, ó sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
s-6
MARK_5.6
Nígbà tí ó sì rí Jésù látòkèrè, ó sí sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
But when he saw Jesus afar off, he ran and worshipped him,
[7] tree
Ó kígbe ohùn rara , ni ṣe tèmi tìrẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀ga Ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ ṣe mi lóró .
s-7
MARK_5.7
Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ni ṣe tèmi tìrẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀ga Ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”
And cried with a loud voice, and said, What have I to do with thee, Jesus, thou Son of the most high God? I adjure thee by God, that thou torment me not.
[8] tree
Nítorí Ó fún un , Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!
s-8
MARK_5.8
Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”
For he said unto him, Come out of the man, thou unclean spirit.
[9] tree
Jésù bi í léèrè , ni orúkọ rẹ? Ẹ̀mí àìmọ́ náà dáhùn , Líjíọ́nì, nítorí àwa pọ̀.
s-9
MARK_5.9
Jésù sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Líjíọ́nì, nítorí àwa pọ̀.”
And he asked him, What is thy name? And he answered, saying, My name is Legion: for we are many.
[10] tree
Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ í bẹ Jésù gidigidi, ó ṣe rán àwọn jáde kúrò agbègbè náà.
s-10
MARK_5.10
Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.
And he besought him much that he would not send them away out of the country.
[11] tree
Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan ń jẹ lẹ́bàá òké.
s-11
MARK_5.11
Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òké.
Now there was there nigh unto the mountains a great herd of swine feeding.
[12] tree
Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jésù , Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọnni awa le è wọ inú wọn lọ.
s-12
MARK_5.12
Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jésù pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọnni kí awa le è wọ inú wọn lọ.”
And all the devils besought him, saying, Send us into the swine, that we may enter into them.
[13] tree
Jésù fún wọn láàyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà ó ìwọ̀n ẹgbàá túká lọ́gán, wọ́n sáré lọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú òkun, wọ́n ṣègbé.
s-13
MARK_5.13
Jésù fún wọn láàyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé.
And forthwith Jesus gave them leave. And the unclean spirits went out, and entered into the swine: and the herd ran violently down a steep place into the sea, (they were about two thousand;) and were choked in the sea.
[14] tree
Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí lọ àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n ń tan ìròyìn náà wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà ó sẹlẹ̀.
s-14
MARK_5.14
Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sá lọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó sẹlẹ̀.
And they that fed the swine fled, and told it in the city, and in the country. And they went out to see what it was that was done.
[15] tree
Nígbà wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n ọkùnrin náà, ẹni ó ẹ̀mí-èṣù, ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ bọ̀ sípọ, ẹ̀rù wọ́n.
s-15
MARK_5.15
Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
And they come to Jesus, and see him that was possessed with the devil, and had the legion, sitting, and clothed, and in his right mind: and they were afraid.
[16] tree
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun ó sẹlẹ̀ ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.
s-16
MARK_5.16
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.
And they that saw it told them how it befell to him that was possessed with the devil, and also concerning the swine.
[17] tree
Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ bẹ Jésù ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀.
s-17
MARK_5.17
Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jésù pé kí ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀.
And they began to pray him to depart out of their coasts.
[18] tree
Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà ó ti ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ òun a lọ.
s-18
MARK_5.18
Bí Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ.
And when he was come into the ship, he that had been possessed with the devil prayed him that he might be with him.
[19] tree
Jésù gbà fún un, ṣùgbọ́n ó fún un , Lọ ilé ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, o sọ fún wọn Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún , àti ó ti ṣàánú fún .
s-19
MARK_5.19
Jésù kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.”
Howbeit Jesus suffered him not, but saith unto him, Go home to thy friends, and tell them how great things the Lord hath done for thee, and hath had compassion on thee.
[20] tree
Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ ròyìn Dekapolisi nípa ohun ńlá Jésù ṣe fún un. Ẹnu ya gbogbo ènìyàn.
s-20
MARK_5.20
Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapolisi nípa ohun ńlá tí Jésù ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.
And he departed, and began to publish in Decapolis how great things Jesus had done for him: and all men did marvel.
[21] tree
Nígbà Jésù ti inú ọkọ̀ rékọjá apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ i etí òkun.
s-21
MARK_5.21
Nígbà tí Jésù sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí òkun.
And when Jesus was passed over again by ship unto the other side, much people gathered unto him: and he was nigh unto the sea.
[22] tree
Ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù à ń ni Jáírù sọ́dọ̀ Jésù, nígbà ó i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
s-22
MARK_5.22
Ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù tí à ń pè ni Jáírù wá sọ́dọ̀ Jésù, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
And, behold, there cometh one of the rulers of the synagogue, Jairus by name; and when he saw him, he fell at his feet,
[23] tree
Ó bẹ̀ ẹ́ gidigidi , Ọmọbìnrin mi lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, fi ọwọ́ rẹ e, ara rẹ̀ , ó .
s-23
MARK_5.23
Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.”
And besought him greatly, saying, My little daughter lieth at the point of death: I pray thee, come and lay thy hands on her, that she may be healed; and she shall live.
[24] tree
Jésù ń a lọ. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
s-24
MARK_5.24
Jésù sì ń bá a lọ. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
And Jesus went with him; and much people followed him, and thronged him.
[25] tree
Obìnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ó ti ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá.
s-25
MARK_5.25
Obìnrin kan sì wà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá.
And a certain woman, which had an issue of blood twelve years,
[26] tree
Ẹni ojú rẹ̀ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, ó ti gbogbo ohun ó , síbẹ̀ kàkà ó san, ó ń burú i.
s-26
MARK_5.26
Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i.
And had suffered many things of many physicians, and had spent all that she had, and was nothing bettered, but rather grew worse,
[27] tree
Nígbà ó gburo iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe, ìdí nìyìí ó fi sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.
s-27
MARK_5.27
Nígbà tí ó sì gburo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.
When she had heard of Jesus, came in the press behind, and touched his garment.
[28] tree
Nítorí ti ó ọkàn rẹ̀ , mo ṣá à fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò .
s-28
MARK_5.28
Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá ṣá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”
For she said, If I may touch but his clothes, I shall be whole.
[29] tree
Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ gbẹ lẹṣẹkẹṣẹ, òun mọ̀ lára rẹ̀ , a òun láradá kúrò nínú àrùn náà.
s-29
MARK_5.29
Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ sì gbẹ lẹṣẹkẹṣẹ, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú àrùn náà.
And straightway the fountain of her blood was dried up; and she felt in her body that she was healed of that plague.
[30] tree
Lọ́gán, Jésù mọ̀ nínú ara rẹ̀ agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó béèrè, Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?
s-30
MARK_5.30
Lọ́gán, Jésù sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”
And Jesus, immediately knowing in himself that virtue had gone out of him, turned him about in the press, and said, Who touched my clothes?
[31] tree
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún un , Ìwọ ọ̀pọ̀ ènìyàn ó rọ̀gbà , ìwọ́ tún ń bèèrè ẹni ó fi ọwọ́ kàn ọ́?
s-31
MARK_5.31
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ́ sì tún ń bèèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”
And his disciples said unto him, Thou seest the multitude thronging thee, and sayest thou, Who touched me?
[32] tree
Ṣíbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ yíká láti ẹni náà, ó fi ọwọ́ kan òun.
s-32
MARK_5.32
Ṣíbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun.
And he looked round about to see her that had done this thing.
[33] tree
Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sọ ohun òun ti ṣe.
s-33
MARK_5.33
Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ ohun tí òun ti ṣe.
But the woman fearing and trembling, knowing what was done in her, came and fell down before him, and told him all the truth.
[34] tree
Jésù fún un , Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ lára : a lọ àlàáfíà, ìwọ ti sàn nínú àrùn rẹ.
s-34
MARK_5.34
Jésù sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá: Má a lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú àrùn rẹ.”
And he said unto her, Daughter, thy faith hath made thee whole; go in peace, and be whole of thy plague.
[35] tree
Jésù ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ láti ilé Jáírù olorí sínágọ́gù , wọ́n fún un , ọmọbìnrin rẹ ti , àti wọn ṣe yọ Jésù lẹ́nu láti , nítorí ó ti pẹ́ .
s-35
MARK_5.35
Bí Jésù sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jáírù olorí sínágọ́gù wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jésù lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.
While he yet spake, there came from the ruler of the synagogue's house certain which said, Thy daughter is dead: why troublest thou the Master any further?
[36] tree
Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó fún Jáírù , bẹ̀rù, à gbà gbọ́ nìkan.
s-36
MARK_5.36
Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jáírù pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbà mí gbọ́ nìkan.”
As soon as Jesus heard the word that was spoken, he saith unto the ruler of the synagogue, Be not afraid, only believe.
[37] tree
Nígbà náà, Jésù ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. jẹ́ ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jáírù, ṣe Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù.
s-37
MARK_5.37
Nígbà náà, Jésù dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jáírù, bí kò ṣe Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù.
And he suffered no man to follow him, save Peter, and James, and John the brother of James.
[38] tree
Nígbà wọ́n ibẹ̀, Jésù i gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn ń sọkún, àti àwọn ń pohùnréré ẹkún.
s-38
MARK_5.38
Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.
And he cometh to the house of the ruler of the synagogue, and seeth the tumult, and them that wept and wailed greatly.
[39] tree
Ó wọ inú ilé lọ, Ó àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè , Èéṣe ẹ̀yin fi ń sọkún ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà , ó sùn lásán ni.
s-39
MARK_5.39
Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.”
And when he was come in, he saith unto them, Why make ye this ado, and weep? the damsel is not dead, but sleepeth.
[40] tree
Wọ́n fi í rẹ́rín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta , ó baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó wọ inú yàrá ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ .
s-40
MARK_5.40
Wọ́n sì fi í rẹ́rín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.
And they laughed him to scorn. But when he had put them all out, he taketh the father and the mother of the damsel, and them that were with him, and entereth in where the damsel was lying.
[41] tree
Ó gba a ọwọ́ , ó , Tàlítà kúùmì ( ó túmọ̀ , ọmọdébìnrin, díde dúró).
s-41
MARK_5.41
Ó gba a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Tàlítà kúùmì” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, díde dúró).
And he took the damsel by the hand, and said unto her, Talitha cumi; which is, being interpreted, Damsel, I say unto thee, arise.
[42] tree
Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà dìde. Ó ń rìn, ẹ̀rù ba wọn, ẹnú ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.
s-42
MARK_5.42
Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.
And straightway the damsel arose, and walked; for she was of the age of twelve years. And they were astonished with a great astonishment.
[43] tree
Jésù kìlọ̀ fún wọn gidigidi wọn ṣe sọ ohun ó ti ṣẹlẹ̀. Ó fún wọn wọn fún ọmọbìnrin náà oúnjẹ.
s-43
MARK_5.43
Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.
And he charged them straitly that no man should know it; and commanded that something should be given her to eat.

Edit as listText viewDependency trees